Isaiah 13

Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Babeli

1 aỌ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Babeli

èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí:
2Gbé àsíá sókè ní orí òkè gbẹrẹfu,
kígbe sí wọn, pè wọ́n
láti wọlé sí ẹnu-ọ̀nà àwọn ọlọ́lá.
3Mo ti pàṣẹ fún àwọn ẹni mímọ́ mi,
mo ti pe àwọn jagunjagun mi
láti gbé ìbínú mi jáde
àwọn tí ń yọ̀ nínú ìṣẹ́gun mi.

4Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè,
gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn
Gbọ́ ìdàrúdàpọ̀ láàrín àwọn ìjọba,
gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè!
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọ
àwọn jagunjagun fún ogun.
5Wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn réré,
láti ìpẹ̀kun ọ̀run wá
Olúwa pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ìbínú rẹ̀,
láti pa gbogbo orílẹ̀-èdè náà run.

6Ẹ hu, nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí,
yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ.
7Nítorí èyí, gbogbo ọwọ́ ni yóò rọ,
ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò rẹ̀wẹ̀sì.
8Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú,
ìrora àti ìpayínkeke yóò dìwọ́n mú,
wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí.
Ẹnìkínní yóò wo ẹnìkejì rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà
ojú wọn á sì gbinájẹ.

9Kíyèsi i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀
ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínú
àti ìrunú gbígbóná—
láti sọ ilẹ̀ náà dahoro,
àti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run.
10 bÀwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti ìkójọpọ̀ wọn
kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn.
Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn yóò di òkùnkùn
àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn.
11Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀,
àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéraga
èmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀.
12Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọn
ju ojúlówóo wúrà lọ,
yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ofiri lọ.
13Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì;
ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀
láti ọwọ́ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ.

14Gẹ́gẹ́ bí egbin tí à ń dọdẹ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́,
ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò padà tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ,
ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò sá padà sí ilẹ̀ abínibí i rẹ̀.
15Ẹnikẹ́ni tí a bá gbámú ni a ó wọ́ nílẹ̀ tuurutu,
gbogbo àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ ni yóò ti ipa idà kú.
16Àwọn ọ̀dọ́mọdé wọn ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ níṣojú wọn,
gbogbo ilẹ̀ wọn ni a ó kó
àwọn aya wọn ni a ó sì bá dàpọ̀.

17Kíyèsi i, èmi yóò ru àwọn Media sókè sí wọn,
àwọn tí kò bìkítà fún fàdákà
tí kò sì ní inú dídùn sí wúrà.
18Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀;
wọn kò ní ṣàánú àwọn ọ̀dọ́mọdé
tàbí kí wọn ṣíjú àánú wo àwọn ọmọdé.
19Babeli, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba
ògo ìgbéraga àwọn ará Babeli
ni Ọlọ́run yóò da ojú rẹ̀ bolẹ̀
gẹ́gẹ́ bí Sodomu àti Gomorra.
20A kì yóò tẹ̀ ibẹ̀ dó mọ́
tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran;
Ará Arabia kì yóò pa àgọ́ níbẹ̀ mọ́,
olùṣọ́-àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.
21 cṢùgbọ́n àwọn ẹranko igbó ni yóò dùbúlẹ̀ níbẹ̀,
àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn,
níbẹ̀ ni àwọn òwìwí yóò máa gbé
níbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́ igbó yóò ti máa bẹ́ kiri.
22Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn,
àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn.

Isaiah 14:1-23

1Olúwa yóò fi àánú hàn fún Jakọbu,

yóò tún Israẹli yàn lẹ́ẹ̀kan sí i
yóò sì fi ìdí wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkára wọn.
Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn,
wọn yóò sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé e Jakọbu.
2Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbà wọ́n
wọn yóò sì mú wọn wá sí ààyè e wọn.
Ilé Israẹli yóò gba àwọn orílẹ̀-èdè
gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin
ní ilẹ̀ Olúwa.
Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùn
wọn yóò sì jẹ ọba lórí àwọn amúnisìn wọn.
3Ní ọjọ́ tí Olúwa yóò fi ìtura fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà, 4ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Babeli pé:

Báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin!
Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí!
5 Olúwa ti dá ọ̀pá ìkà náà,
ọ̀pá àwọn aláṣẹ,
6èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀
pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró,
nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè
pẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin.
7Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà,
wọ́n bú sí orin.
8Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn igi junifa àti àwọn
igi kedari ti Lebanoni
ń yọ̀ lórí rẹ wí pé,
“Níwọ́n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí,
kò sí agégi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.”

9Ibojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni a ru sókè
láti pàdé rẹ ní ìpadàbọ̀ rẹ̀
ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ sókè láti wá kí ọ
gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé
ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ wọn
gbogbo àwọn tí ó jẹ ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè.
10Gbogbo wọn yóò dáhùn,
wọn yóò wí fún ọ wí pé,
“Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú
ìwọ náà ti dàbí wa.”
11Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì,
pẹ̀lú ariwo àwọn dùùrù rẹ,
àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ
àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀.

12Báwo ni ìwọ ṣe ṣubú lulẹ̀ láti ọ̀run wá,
ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà!
A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé
Ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba rí!
13Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé,
“Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run;
Èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè
ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run,
Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpéjọ
ní ṣóńṣó orí òkè mímọ́.
14Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọsánmọ̀;
Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá-ògo.”
15Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọ
lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun.

16Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ,
wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ:
“Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtì
tí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.
17Ẹni tí ó sọ ayé di aginjù,
tí ó sì pa ìlú ńláńlá rẹ̀ run
tí kò dá àwọn òǹdè rẹ̀ sílẹ̀ láti padà sílé?”

18Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè ni a tẹ́ sílẹ̀
ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀.
19Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojì
gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀sílẹ̀,
àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀,
àwọn tí idà ti gún,
àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun.
Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀,
20A kò ní sin ọ́ pẹ̀lú wọn,
nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́
o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ.


Ìran àwọn ìkà
ni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́.
21Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹ
nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn,
wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀
kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlú u wọn.

22“Èmi yóò dìde sókè sí wọn,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
“Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Babeli àti àwọn tí ó sálà,
àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,”
ni Olúwa wí.
23Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwí
àti sí irà;
Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a,
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Copyright information for YorBMYO